Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu Keji 1:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.

6. Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.

7. Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.

8. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.

9. Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ.

10. Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín tí kò mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé. Ẹ má tilẹ̀ kí i, “Kú ààbọ̀.”

11. Ẹni tí ó bá kí i di alábàápín ninu àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.

12. Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.

Ka pipe ipin Johanu Keji 1