Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jakọbu 3:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde.

13. Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn.

14. Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́.

15. Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú.

16. Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀.

17. Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè.

18. Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia.

Ka pipe ipin Jakọbu 3