Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 9:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn eṣú wọnyi dàbí àwọn ẹṣin tí a dì ní gàárì láti lọ sójú ogun. Adé wà ní orí wọn tí ó dàbí adé wúrà. Ojú wọn dàbí ojú eniyan.

8. Irun wọn dàbí irun obinrin. Eyín wọn dàbí ti kinniun.

9. Wọ́n ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ wọn dàbí ìró ọpọlọpọ ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin tí wọn ń sáré lọ sójú ogun.

10. Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un.

11. Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun.

12. Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí.

13. Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun.

14. Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.”

15. Ni wọ́n bá dá àwọn angẹli mẹrin náà sílẹ̀. A ti pèsè wọn sílẹ̀ fún wakati yìí, ní ọjọ́ yìí, ninu oṣù yìí, ní ọdún yìí pé kí wọ́n pa ìdámẹ́ta gbogbo eniyan.

Ka pipe ipin Ìfihàn 9