Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 9:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun.

12. Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí.

13. Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun.

14. Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.”

15. Ni wọ́n bá dá àwọn angẹli mẹrin náà sílẹ̀. A ti pèsè wọn sílẹ̀ fún wakati yìí, ní ọjọ́ yìí, ninu oṣù yìí, ní ọdún yìí pé kí wọ́n pa ìdámẹ́ta gbogbo eniyan.

16. Iye àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000,000). Mo gbọ́ iye wọn.

17. Bí àwọn ẹṣin ọ̀hún ati àwọn tí ó gùn wọ́n ti rí lójú mi, lójú ìran nìyí: wọ́n gba ọ̀já ìgbàyà tí ó pọ́n bí iná, ó dàbí àyìnrín, ó tún rí bí imí-ọjọ́. Orí àwọn ẹṣin náà dàbí orí kinniun. Wọ́n ń yọ iná, ati èéfín ati imí-ọjọ́ lẹ́nu.

18. Ohun ijamba mẹta yìí tí ó ń yọ jáde lẹ́nu wọn pa ìdá mẹta àwọn eniyan.

19. Agbára àwọn ẹṣin wọnyi wà ní ẹnu wọn ati ní ìrù wọn. Nítorí ìrù wọn dàbí ejò, wọ́n ní orí. Òun sì ni wọ́n fi ń ṣe àwọn eniyan léṣe.

Ka pipe ipin Ìfihàn 9