Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 9:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Angẹli karun-un wá fun kàkàkí rẹ̀, mo bá rí ìràwọ̀ kan tí ó ti ojú ọ̀run já bọ́ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún ìràwọ̀ yìí ní kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀.

2. Ó ṣí kànga náà, èéfín bá yọ láti inú kànga yìí, ó dàbí èéfín iná ìléru ńlá. Oòrùn ati ojú ọ̀run bá ṣókùnkùn nítorí èéfín tí ó jáde láti inú kànga náà.

3. Àwọn eṣú ti tú jáde láti inú èéfín náà, wọ́n lọ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún wọn ní agbára bíi ti àkeekèé ayé.

4. A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe.

5. A kò gbà pé kí wọ́n pa wọ́n, oró ni kí wọ́n dá wọn fún oṣù marun-un, kí wọ́n dá wọn lóró bí ìgbà tí àkeekèé bá ta eniyan.

6. Ní ọjọ́ náà àwọn eniyan yóo máa wá ikú ṣugbọn wọn kò ní kú; wọn yóo tọrọ ikú, ṣugbọn kò ní súnmọ́ wọn.

7. Àwọn eṣú wọnyi dàbí àwọn ẹṣin tí a dì ní gàárì láti lọ sójú ogun. Adé wà ní orí wọn tí ó dàbí adé wúrà. Ojú wọn dàbí ojú eniyan.

8. Irun wọn dàbí irun obinrin. Eyín wọn dàbí ti kinniun.

9. Wọ́n ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ wọn dàbí ìró ọpọlọpọ ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin tí wọn ń sáré lọ sójú ogun.

10. Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un.

11. Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun.

12. Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí.

Ka pipe ipin Ìfihàn 9