Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 8:12-13 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru.

13. Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!”

Ka pipe ipin Ìfihàn 8