Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 5:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye.

12. Wọ́n ń kígbe pé,“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ síláti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.”

13. Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹnití ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”

14. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.

Ka pipe ipin Ìfihàn 5