Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í.

2. Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?”

3. Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó.

4. Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó.

5. Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.”

6. Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé.

7. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.

Ka pipe ipin Ìfihàn 5