Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 4:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé,“Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!Oluwa Ọlọrun Olodumare.Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii,tí ó sì ń bọ̀ wá.”

9. Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae,

10. àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé,

11. “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára.Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà,nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 4