Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 3:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.

12. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi.

13. “Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.

14. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé:“Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní

15. Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan.

16. Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi.

17. Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò.

18. Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran.

19. Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.

20. Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun.

21. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 3