Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 20:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.

9. Wọ́n gba gbogbo ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n wá yí àwọn eniyan Ọlọrun ká ati ìlú tí Ọlọrun fẹ́ràn. Ni iná bá sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó bá jó wọn run patapata.

10. A bá ju Èṣù tí ó ń tàn wọ́n jẹ sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá, níbi tí ẹranko náà ati wolii èké náà wà, tí wọn yóo máa joró tọ̀sán-tòru lae ati laelae.

11. Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́.

12. Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀.

13. Gbogbo àwọn tí wọ́n kú sinu òkun tún jáde sókè. Gbogbo òkú tí ó wà níkàáwọ́ ikú ati àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú ni wọ́n tún jáde. A wá ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

14. Ni a bá ju ikú ati ipò òkú sinu adágún iná. Adágún iná yìí ni ikú keji.

Ka pipe ipin Ìfihàn 20