Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 20:6-8 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún.

7. Nígbà tí ẹgbẹrun ọdún bá parí a óo tú Satani sílẹ̀ ninu ẹ̀wọ̀n tí ó ti wà.

8. Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.

Ka pipe ipin Ìfihàn 20