Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 20:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo wá rí angẹli kan tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó mú kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn pupọ náà lọ́wọ́ ati ẹ̀wọ̀n gígùn.

2. Ó bá ki Ẹranko Ewèlè náà mọ́lẹ̀, ejò àtijọ́ náà tíí ṣe Èṣù tabi Satani, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é fún ẹgbẹrun ọdún.

3. Ó bá jù ú sinu kànga tí ó jìn pupọ náà, ó pa ìdérí rẹ̀ dé mọ́ ọn lórí. Ó bá fi èdìdì dì í kí ó má baà tan àwọn eniyan jẹ mọ́ títí ẹgbẹrun ọdún yóo fi parí. Lẹ́yìn náà, a óo dá a sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

4. Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.

Ka pipe ipin Ìfihàn 20