Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 19:8-21 BIBELI MIMỌ (BM)

8. A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.”

9. Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.”

10. Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.”Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii.

11. Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun.

12. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára.

13. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

14. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́.

15. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.

16. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”

17. Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun,

18. kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.”

19. Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun.

20. A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá.

21. Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn.

Ka pipe ipin Ìfihàn 19