Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 17:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè.

16. Nígbà tí ó bá yá, àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí yìí ati ẹranko náà, yóo kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn óo tú u sí ìhòòhò, wọn óo bá fi í sílẹ̀ ní ahoro. Wọn óo jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn óo bá dá iná sun ún títí yóo fi jóná ráúráú.

17. Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ.

Ka pipe ipin Ìfihàn 17