Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 17:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi.

2. Àwọn ọba ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn tí ń gbé inú ayé ti mu ninu ọtí àgbèrè rẹ̀.”

3. Ẹ̀mí gbé mi, ni angẹli yìí bá gbé mi lọ sinu aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni mo ti rí obinrin tí ó gun ẹranko pupa kan, tí àwọn orúkọ àfojúdi kún ara rẹ̀. Ẹranko náà ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.

4. Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀.

5. Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.”

6. Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà.

7. Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.

Ka pipe ipin Ìfihàn 17