Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 16:16-21 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu.

17. Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!”

18. Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé.

19. Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀.

20. Omi bo gbogbo àwọn erékùṣù, a kò sì rí ẹyọ òkè kan mọ́.

21. Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba.

Ka pipe ipin Ìfihàn 16