Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 16:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Angẹli karun-un da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà, ó bá sọ ìjọba rẹ̀ di òkùnkùn. Àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gé ara wọn láhọ́n jẹ nítorí ìrora wọn,

11. wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun ọ̀run nítorí ìrora wọn ati nítorí egbò ara wọn, dípò kí wọ́n ronupiwada fún ohun tí wọ́n ti ṣe.

12. Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn.

13. Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà.

14. Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.

15. “Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 16