Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 15:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa?Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ?Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé,nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá,wọn yóo júbà níwájú rẹ,nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”

5. Lẹ́yìn èyí mo tún rí Tẹmpili tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Àgọ́-Ẹ̀rí wà ninu rẹ̀.

6. Àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn meje níkàáwọ́ jáde láti inú Tẹmpili náà wá, wọ́n wọ aṣọ funfun tí ó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. Wúrà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà wọn.

7. Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.

8. Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí.

Ka pipe ipin Ìfihàn 15