Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 14:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.

2. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.

3. Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé.

4. Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan.

5. Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn.

6. Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè.

7. Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”

8. Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”

9. Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀,

10. yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan.

11. Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”

12. Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà.

13. Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.”Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 14