Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 11:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọ́n fún mi ní ọ̀pá kan, bí èyí tí wọ́n fi ń wọn aṣọ. Wọ́n sọ fún mi pé, “Dìde! Lọ wọn Tẹmpili Ọlọrun ati pẹpẹ ìrúbọ, kí o ka iye àwọn tí wọ́n n jọ́sìn níbẹ̀.

2. Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.

3. N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”

4. Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú.

6. Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́.

7. Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n.

8. Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti.

9. Àwọn eniyan láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo orílẹ̀-èdè yóo máa wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀. Wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n sin wọ́n.

10. Àwọn ọmọ aráyé yóo máa yọ̀ wọ́n, inú wọn yóo sì máa dùn. Wọn yóo máa fún ara wọn lẹ́bùn. Nítorí pé ìyọlẹ́nu ni àwọn akéde meji wọnyi jẹ́ fún àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé.

11. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀ yìí, èémí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ inú wọn, ni wọ́n bá jí, wọn bá dìde dúró. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó rí wọn gan-an.

Ka pipe ipin Ìfihàn 11