Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 10:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.”

5. Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run,

6. ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́.

7. Ní ọjọ́ tí angẹli keje bá fọhùn, nígbà tí ó bá fẹ́ fun kàkàkí tirẹ̀, àṣírí ète Ọlọrun yóo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.

8. Mo tún gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó sọ fún mi pé, “Lọ gba ìwé tí ó wà ni ṣíṣí tí ó wà lọ́wọ́ angẹli tí ó dúró lórí òkun ati lórí ilẹ̀.”

9. Mo bá lọ sọ́dọ̀ angẹli náà, mo ní kí ó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó ní, “Gbà, kí o jẹ ẹ́. Yóo dùn ní ẹnu rẹ bí oyin, ṣugbọn yóo korò ní ikùn rẹ.”

10. Mo bá gba ìwé náà ní ọwọ́ angẹli yìí, mo bá jẹ ẹ́. Ó dùn bí oyin ní ẹnu mi. Ṣugbọn nígbà tí mo gbé e mì, ó korò ní ikùn mi.

11. Wọ́n bá sọ fún mi pé, “O níláti tún kéde fún ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ati oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ati àwọn orílẹ̀-èdè, ati ọpọlọpọ ìjọba.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 10