Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 9:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya.

23. Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á.

24. Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á.

25. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú.

26. Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.

27. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku.

28. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa,

29. ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á.

30. Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu.

31. Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 9