Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 8:34-40 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?”

35. Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un.

36. Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [

37. Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”]

38. Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi.

39. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀.

40. Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 8