Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 5:3-18 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà?

4. Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.”

5. Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́.

6. Àwọn géńdé bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e lọ sin.

7. Nígbà tí ó tó bíi wakati mẹta lẹ́yìn náà, iyawo Anania wọlé dé. Kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

8. Peteru bi í pé, “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ ta ilẹ̀ náà nìyí?”Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye tí a tà á ni.”

9. Peteru bá bi í pé, “Kí ló dé tí ẹ jọ fi ohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Oluwa wò? Wo ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n lọ sin ọkọ rẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn yóo gbé ìwọ náà jáde.”

10. Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀.

11. Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo ìjọ ati gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi.

12. Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni.

13. Kò sí ẹni tí ó láyà ninu àwọn ìyókù láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ wọn níyì lọ́dọ̀ àwọn eniyan.

14. Àwọn tí wọ́n gba Oluwa gbọ́ túbọ̀ ń darapọ̀ mọ́ wọn, lọkunrin ati lobinrin.

15. Nígbà tí ó yá, àwọn eniyan a máa gbé àwọn aláìsàn wá sí títì lórí ẹní ati lórí ibùsùn, pé kí òjìji Peteru lè ṣíji bò wọ́n nígbà tí ó bá ń kọjá.

16. Ọpọlọpọ àwọn eniyan wá láti agbègbè ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn ati àwọn tí ẹ̀mí burúkú ń dà láàmú wá; a sì mú gbogbo wọn lára dá.

17. Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀.

18. Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 5