Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 5:29-40 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.

30. Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde.

31. Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli.

32. Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.”

33. Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n.

34. Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀.

35. Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí.

36. Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo.

37. Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká.

38. To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́.

39. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!”Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40. Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 5