Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania pẹlu Safira, iyawo rẹ̀, ta ilẹ̀ kan.

2. Ọkunrin yìí yọ sílẹ̀ ninu owó tí wọ́n rí lórí rẹ̀, ó bá mú ìyókù wá siwaju àwọn aposteli. Iyawo rẹ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀.

3. Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà?

4. Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.”

5. Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́.

6. Àwọn géńdé bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e lọ sin.

7. Nígbà tí ó tó bíi wakati mẹta lẹ́yìn náà, iyawo Anania wọlé dé. Kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 5