Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 4:23-37 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn.

24. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,

25. ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé,‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí,tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán?

26. Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan,láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’

27. Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,

28. àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

29. Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

30. Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.”

31. Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

32. Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni.

33. Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn.

34. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá,

35. wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní.

36. Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”)

37. ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 4