Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 4:12-28 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.”

13. Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.

14. Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ.

15. Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé,

16. “Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀.

17. Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.”

18. Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́.

19. Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò.

20. Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.”

21. Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.

22. Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ.

23. Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn.

24. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,

25. ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé,‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí,tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán?

26. Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan,láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’

27. Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,

28. àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 4