Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 3:21-26 BIBELI MIMỌ (BM)

21. ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀.

22. Mose ṣá ti sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan bí èmi dìde láàrin àwọn arakunrin yín. Òun ni kí ẹ gbọ́ràn sí lẹ́nu ninu ohun gbogbo tí ó bá sọ fun yín.

23. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sí wolii náà lẹ́nu, píparun ni a óo pa á run patapata láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.’

24. Gbogbo àwọn wolii, láti ìgbà Samuẹli ati àwọn tí ó dé lẹ́yìn rẹ̀, fi ohùn ṣọ̀kan sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ń sọ nípa àkókò yìí.

25. Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’

26. Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 3