Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 3:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ẹ sẹ́ ẹni Ọlọrun ati olódodo, ẹ wá bèèrè pé kí wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀ fun yín;

15. ẹ pa orísun ìyè. Òun yìí ni Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Àwa gan-an ni ẹlẹ́rìí pé bẹ́ẹ̀ ló rí.

16. Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín.

17. “Ṣugbọn nisinsinyii, ará, mo mọ̀ pé ẹ kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjòyè yín náà kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é.

18. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe mú ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wolii rẹ̀ ṣẹ, pé Mesaya òun níláti jìyà.

19. Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.

20. Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu,

21. ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 3