Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 28:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí a ti gúnlẹ̀ ní alaafia tán ni a tó mọ̀ pé Mẹlita ni wọ́n ń pe erékùṣù náà.

2. Àwọn ará ibẹ̀ ṣe ìtọ́jú wa lọpọlọpọ. Wọ́n fi ọ̀yàyà gba gbogbo wa. Wọ́n dáná fún wa nítorí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òtútù sì mú.

3. Nígbà tí Paulu di ìdì igi kan, tí ó dà á sinu iná, bẹ́ẹ̀ ni paramọ́lẹ̀ kan yọ nígbà tí iná rà á, ló bá so mọ́ Paulu lọ́wọ́.

4. Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.”

5. Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i.

6. Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!”

7. Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò.

8. Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn.

9. Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn.

10. Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà.

11. Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 28