Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 27:23-41 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní,

24. ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’

25. Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí.

26. Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.”

27. Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀.

28. Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita.

29. Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́.

30. Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun.

31. Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.”

32. Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ.

33. Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun.

34. Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.”

35. Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́.

36. Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun.

37. Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276).

38. Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i.

39. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí èbúté ṣugbọn wọn kò mọ ibẹ̀. Wọ́n wá ṣe akiyesi ibìkan tí òkun ti wọ ààrin ilẹ̀ tí ó ní iyanrìn. Wọ́n rò pé bóyá àwọn lè tukọ̀ dé èbúté ibẹ̀.

40. Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté.

41. Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 27