Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 27:18-33 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun.

19. Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun.

20. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́.

21. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí.

22. Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò.

23. Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní,

24. ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’

25. Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí.

26. Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.”

27. Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀.

28. Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita.

29. Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́.

30. Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun.

31. Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.”

32. Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ.

33. Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 27