Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 27:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete.

13. Nígbà tí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ jẹ́jẹ́ láti apá gúsù, wọ́n rò pé ó ti bọ́ sí i fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n bá ṣíkọ̀, wọ́n ń pẹ́ ẹ̀bá Kirete lọ.

14. Kò pẹ́ pupọ ni afẹ́fẹ́ líle kan láti erékùṣù náà bá bì lu ọkọ̀. Wọ́n ń pe afẹ́fẹ́ náà ní èyí tí ó wá láti àríwá ìlà oòrùn.

15. Afẹ́fẹ́ líle yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí taari ọkọ̀. Nítorí pé kò sí ọ̀nà láti fi yí ọkọ̀, kí ó kọjú sí atẹ́gùn yìí, a fi í sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ máa gbé e lọ.

16. A sinmi díẹ̀ nígbà tí a gba gúsù erékùṣù kékeré kan tí ó ń jẹ́ Kauda kọjá. Níbẹ̀, a fi tipátipá so ọkọ̀ kékeré tí ó wà lára ọkọ̀ ńlá wa, kí ó má baà fọ́.

17. Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ.

18. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun.

19. Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun.

20. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́.

21. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí.

22. Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò.

23. Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní,

24. ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’

25. Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí.

26. Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 27