Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 27:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu.

2. A bá wọ ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ń ti Adiramitu bọ̀ tí ó fẹ́ lọ sí ibi mélòó kan ní Esia. Ọkọ̀ bá ṣí; Arisitakọsi ará Tẹsalonika, ní ilẹ̀ Masedonia, ń bá wa lọ.

3. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò.

4. Láti ibẹ̀, a ṣíkọ̀, nítorí pé afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wa, a gba apá Kipru níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ.

5. A la agbami lọ sí apá èbúté Silisia ati Pamfilia títí a fi dé ìlú Mira ní ilẹ̀ Lisia.

6. Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún tí ó ń mú wa lọ ti rí ọkọ̀ Alẹkisandria kan tí ó ń lọ sí Itali. Ni a bá wọ̀ ọ́.

7. Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone.

8. Tipátipá ni a fi ń lọ lẹ́bàá èbúté títí a fi dé ibìkan tí wọn ń pè ní Èbúté-rere tí kò jìnnà sí ìlú Lasia.

9. A pẹ́ níbẹ̀. Ewu ni bí a bá fẹ́ máa bá ìrìn àjò wa lọ nítorí ọjọ́ ààwẹ̀ ti kọjá. Paulu bá gbà wọ́n níyànjú;

10. ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 27