Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 24:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.”

23. Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

24. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀.

25. Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ tirẹ̀ nípa ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu, ati ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹliksi. Ó bá sọ fún Paulu pé, “Ó tó gẹ́ẹ́ lónìí. Máa lọ. Nígbà tí mo bá ráyè n óo tún ranṣẹ pè ọ́.”

26. Sibẹ ó ń retí pé Paulu yóo fún òun ní owó. Nítorí náà, a máa ranṣẹ pè é lemọ́lemọ́ láti bá a sọ̀rọ̀.

27. Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 24