Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 24:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú.

16. Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.

17. “Ó ti tó ọdún mélòó kan tí mo ti dé Jerusalẹmu gbẹ̀yìn. Ìtọrẹ àánú ni mo mú wá fún àwọn orílẹ̀-èdè mi, kí n sì rúbọ.

18. Níbi tí mo gbé ń ṣe èyí, wọ́n rí mi ninu Tẹmpili. Mo ti wẹ ara mi mọ́ nígbà náà. N kò kó èrò lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fa ìjàngbọ̀n.

19. Ṣugbọn àwọn Juu kan láti Esia wà níbẹ̀. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n wá siwaju yín bí wọn bá ní ẹ̀sùn kan sí mi.

20. Tabi, kí àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín fúnra wọn sọ nǹkan burúkú kan tí wọ́n rí pé mo ṣe nígbà tí mo wà níwájú ìgbìmọ̀.

21. Àfi gbolohun kan tí mo sọ nígbà tí mo dúró láàrin wọn, pé, ‘Ìdí tí a fi mú mi wá fún ìdájọ́ níwájú yín lónìí ni pé mo ní igbagbọ pé àwọn òkú yóo jinde.’ ”

22. Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.”

23. Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

24. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 24