Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 23:20-35 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní.

21. Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.”

22. Ọ̀gágun bá ní kí ọdọmọkunrin náà máa lọ. Ó kìlọ̀ fún un pé kí ó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé ó ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó òun létí.

23. Ọ̀gágun náà bá pe meji ninu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ mú igba ọmọ-ogun ati aadọrin ẹlẹ́ṣin ati igba ọmọ-ogun tí ó ní ọ̀kọ̀. Ẹ óo lọ sí Kesaria. Kí ẹ múra láti lọ ní agogo mẹsan-an alẹ́.

24. Ẹ tọ́jú àwọn ẹṣin tí Paulu yóo gùn, kí ẹ sìn ín dé ọ̀dọ̀ Fẹliksi gomina ní alaafia.”

25. Ó wá kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé náà lọ báyìí:

26. “Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín.

27. Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni.

28. Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn.

29. Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n.

30. Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.”

31. Àwọn ọmọ-ogun ṣe bí a ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n mú Paulu lóru lọ sí ìlú Antipatiri.

32. Ní ọjọ́ keji wọ́n fi Paulu sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin, wọ́n pada sí àgọ́ wọn.

33. Àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin bá a lọ sí Kesaria. Wọ́n fún gomina ní ìwé, wọ́n sì fa Paulu lé e lọ́wọ́.

34. Gomina ka ìwé náà. Ó wá wádìí pé apá ibo ni Paulu ti wá. Wọ́n sọ fún un pé ní agbègbè Silisia ni.

35. Ó bá sọ fún un pé, “N óo gbọ́ ẹjọ́ rẹ nígbà tí àwọn tí ó fi ẹjọ́ rẹ sùn náà bá dé.” Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ Paulu ní ààfin Hẹrọdu.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 23