Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 21:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.”

15. Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu.

16. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́.

17. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀.

18. Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ.

19. Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

20. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.

21. Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́.

22. Èwo ni ṣíṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti dé.

23. Bí a bá ti wí fún ọ ni kí o ṣe. Àwọn ọkunrin mẹrin kan wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́.

24. Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́.

25. Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 21