13. Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.”
14. Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.”
15. Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu.
16. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́.
17. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀.
18. Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ.
19. Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.
20. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.
21. Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́.