Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 2:6-19 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀.

7. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi?

8. Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀?

9. Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia,

10. ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu,

11. àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.”

12. Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?”

13. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!”

14. Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.

15. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni.

16. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé,

17. ‘Ọlọrun sọ pé,“Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn,n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan.Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran,àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá.

18. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí misórí àwọn ẹrukunrin miati sí orí àwọn ẹrubinrin mi,àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

19. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run,ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé;ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 2