Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 19:28-39 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!”

29. Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré.

30. Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un.

31. Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú.

32. Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ!

33. Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀.

34. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!”

35. Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run?

36. Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun.

37. Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa.

38. Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀.

39. Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 19