Àwọn mélòó kan ninu àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kó ìwé idán wọn jọ, wọ́n bá dáná sun wọ́n lójú gbogbo eniyan. Nígbà tí wọ́n ṣírò iye owó àwọn ìwé ọ̀hún, wọ́n rí i pé ó tó ọ̀kẹ́ meji ààbọ̀ (50,000) owó fadaka.