Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 17:19-34 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?

20. Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

21. (Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.)

22. Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré.

23. Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.

24. Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́;

25. bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.

26. Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.

27. Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa.

28. Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé:‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé,tí à ń rìn kiri,tí a wà láàyè.’Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní,‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’

29. Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan.

30. Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada.

31. Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.”

32. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.”

33. Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn.

34. Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 17