Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 16:25-34 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn.

26. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú.

27. Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni.

28. Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.”

29. Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila.

30. Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?”

31. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.”

32. Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀.

33. Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi.

34. Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 16