Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 15:35-41 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa.

36. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ Paulu wí fún Banaba pé, “Jẹ́ kí á pada lọ bẹ àwọn onigbagbọ wò ní gbogbo ìlú tí a ti waasu ọ̀rọ̀ Oluwa, kí a rí bí wọ́n ti ń ṣe.”

37. Banaba fẹ́ mú Johanu tí à ń pè ní Maku lọ.

38. Ṣugbọn Paulu kò rò pé ó yẹ láti mú un lọ, nítorí ó pada lẹ́yìn wọn ní Pamfilia, kò bá wọn lọ títí dé òpin iṣẹ́ náà.

39. Àríyànjiyàn náà le tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi pínyà, tí olukuluku fi bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Banaba mú Maku, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru.

40. Paulu mú Sila ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn onigbagbọ ti fi í lé oore-ọ̀fẹ́ Oluwa lọ́wọ́.

41. Ó gba Siria ati Silisia kọjá, ó ń mú àwọn ìjọ lọ́kàn le.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 15