Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 15:22-35 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ.

23. Wọ́n fi ìwé rán wọn, pé:“Àwa aposteli ati àwa alàgbà kí ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ní Antioku, Siria ati Silisia; a kí yín bí arakunrin sí arakunrin.

24. A gbọ́ pé àwọn kan láti ọ̀dọ̀ wa ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí ọkàn yín balẹ̀. A kò rán wọn níṣẹ́.

25. A ti wá pinnu, gbogbo wa sì fohùn sí i, a wá yan àwọn eniyan láti rán si yín pẹlu Banaba ati Paulu, àwọn àyànfẹ́ wa,

26. àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

27. Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín.

28. Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi:

29. kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè. Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!”

30. Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà.

31. Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀.

32. Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le.

33. Wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀, ni àwọn ìjọ bá fi tayọ̀tayọ̀ rán wọn pada lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. [

34. Ṣugbọn Sila pinnu láti dúró níbẹ̀.]

35. Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 15