Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 14:5-20 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa.

6. Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn.

7. Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀.

8. Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí.

9. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá.

10. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn.

11. Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!”

12. Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀.

13. Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n.

14. Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé,

15. “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn.

16. Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.

17. Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.”

18. Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n.

19. Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú.

20. Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 14