Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 14:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!”

12. Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀.

13. Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n.

14. Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé,

15. “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn.

16. Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.

17. Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.”

18. Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n.

19. Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú.

20. Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba.

21. Wọ́n waasu ìyìn rere ní ìlú náà, àwọn eniyan pupọ sì di onigbagbọ. Wọ́n bá pada sí Listira ati Ikoniomu ati Antioku ní Pisidia.

22. Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro.

23. Wọ́n yan àgbà ìjọ fún wọn ninu ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí wọ́n ti gbadura, tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé ọwọ́ Oluwa tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé.

24. Wọ́n wá gba Pisidia kọjá lọ sí Pamfilia.

25. Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia.

26. Wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí Antioku ní Siria níbi tí wọ́n ti kọ́ fi wọ́n sábẹ́ ojurere Ọlọrun fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 14